You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Agbésùnmọ̀mí kólu Plateau, ṣekúpa ológun àti fijilanté 20
Ko din ni ogun agbofinro ati fijilante ti awọn agbesunmọmi gbẹmi wọn lẹyin ti wọn dena de wọn ni Wanka ati Garga, to wa ni ijọba ibilẹ Kanam, nipinlẹ Plateau.
Ajọ Kanam Development Association (KADA) lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan ti akọwe rẹ, ND Shehu Kanam ati alaga rẹ Garba G. Aliyu buwọlu niluu Dengi.
Ẹgbẹ naa sọ pe agbofinro mejila, ninu eyii ti ọgagun meji wa lara wọn, to fi mọ fijilante mẹjọ to n ran awọn agbofinro naa lọwọ lati daabo bo agbegbe ọhun ni ikọlu naa mu ẹmi wọn lọ.
Gẹgẹ bii ohun ti KADA sọ, inu ọkọ meji lawọn agbofinro naa wa ti wọn n kaakiri awọn ilu naa fun abo awọn olugbe ibẹ ki awọn agbesunmọmi naa to kọlu wọn pẹlu oniruru nnkan ija oloro lọwọ wọn.
Nnnkan bii aago meji ọsan n ikọlu naa waye lọjọ Ẹti.
Wọn ni "Nigba ti wọn kọju ibọn si ara wọn, orilẹeede wa padanu awọn akinkanju loju ija.
"Iku wọn jẹ eyii dun wa gidi, ati eyii ti a ko ni tẹwọgba rara."
Wọn sọ siwaju si pe awọn eeyan abule naa ti ko lagbara lawọn oloogbe ọhun n daabo ki wọn to padanu ẹmi wọn.
Ẹgbẹ naa fikun pe lẹyin ikọlu naa lawọn agbesunmọmi ọhun tun kọlu ilu Kyaram nibi ti wọn ti ji ẹgbẹlẹgbẹ dukia araalu, to fi mọ awọn maalu ti wọn n sin nibẹ lọ.
O fikun pe yatọ si awọn ibi ti wọn kọlu yii, wọn tun maa n kọlu awọn agbegbe mii ni Garga, Kyaram, Gyambau atawọn ilu to wa ni ala awọn ipinlẹ Plateau, Taraba ati Bauchi.
Ṣaaju ikọlu naa ni wọn ti kọkọ ke gbajare si ijọba nipa eto abo to mẹhẹ lagbagbe naa amọ wọn ni ijọba ko kọbi ara si awọn.
Ni bayii, wọn ti wa ke si ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ naa ki wọn mu eto abo agbegbe naa lọkunkundun lọna ati daabo ẹmi ati dukia araalu.
KADA tun n bere pe ki ijọba da awọn akọṣẹmọṣe ologun si Garga, Kyaram, Gyambau, Wanka atawọn agbegbe to yi ka ki irufẹ ikọlu bẹẹ ma ba waye mọ.
Wọn tun ni ki awọn agbofinro maa yi awọn aala ipinlẹ Plateau–Taraba–Bauchi ka nitori awọn agbegbe naa gan lawọn ọdaran n farapamọ si julọ.